- f Oluwa ni Ọba;
Ẹ bọ Oluwa nyin:
Ẹni kiku, ṣọpẹ,
Y’ ayò ‘ṣẹgun titi
ff Gb’ ọkàn at’ ohùn nyin soke
“Ẹ yọ,” mo si tun wi, “Ẹ yọ̀.”
- Olugbala jọba,
Ọlọrun otitọ;
‘Gbat’ o wẹ ‘ṣẹ wa nù,
O goke lọ joko;
ff Gb’ ọkàn at’ ohùn, &c
- O mbẹ lọdọ Baba,
Titi gbogbo ọta,
Yio tẹri wọn ba,
Nipa aṣẹ Tirẹ̀.
ff Gb’ ọkàn at’ ohùn, &c
- Yọ̀ n’ ireti ogo
p Onidajọ mbọ̀ wa;
Lati mu ‘ranṣẹ Rẹ̀
Lọ ‘le aiyeraiye.
A fẹ gbohun Angẹl nla na,
ff Ipè y’o dun wipe, “Ẹ yo,” Amin.