- f Jesu kigbe pe, “Emi de,
T’ emi ti ifẹ nla”
Ọkan mi dahun pe, “Ma bọ̀,”
K’ o mu igbala wá.
- Wà, gbà ọran Baba Rẹ rò;
Si mu ogo Rẹ ràn;
f Wá, ji okú iranṣẹ Rẹ,
K’o si sọ wọn d’ ọtun.
- Ma bọ̀ wà ´larin ogun Rẹ
Lati gb’ orukọ wọn;
K’ o si m’ ajọ kikun pada
Lati y’ itẹ Rẹ ka.
- Olurapada, wá kánkán,
Mu ọjọ nla ni wá.
mf Wa, k’ ọkàn wa má bà daku,
Nitori pipẹ Rẹ. Amin.