- Oru bù kọja tan
Ọsan kù si dẹdẹ̀;
Iboju fẹrẹ̀ ya
T’o bo Olugbala;
Sanmà ti o di wa loju
L’ a fẹrẹ tu kakiri na
- f Ẹ gb’ ori nyin sokè,
Igbala sunmọ ‘le,
Wò bi orùn ti ràn,
Oju ọrun mọlẹ;
ff Enia mimọ́, ẹ si mà yọ̀,
Oluwa fẹrẹ f’ ara han,
- B’ enia nrẹrin nyin,
Ti nwọn ko fẹ́ gbagbọ,
Ẹnyin gb’ ọ̀rọ Rẹ̀ gbọ́,
On kò le tan nyin jẹ,
Nigbati aiye ba kọja,
Ẹnyin o ri ogo Rẹ̀ na.
- Fun nyin ni Oluwa,
Pesè ile didan;
Kò si ‘kanu nibẹ
Kik’ ayọ̀ l’ o kun ‘bẹ;
mf Ẹnyin mimọ, bẹrẹ si ‘yo,
Ẹ fẹrẹ gbohun Angel na. Amin