- Onidajọ na de, O de !
Bẹni pè keje ti ndùn nwi,
Manamana nkọ, àrá nsán,
Onigbagbọ y’o ti yọ̀ to !
- A ngbọ, Angẹl ọrun nwipe,
Jesu Oluwa wa d’ade,
Or’-ọfẹ l’ On fi ddamurè,
Ogo l’ On fi ṣ’ ọ̀ṣọ́ boju.
- ‘Wọ sọkalẹ lor’ itẹ Rẹ
O gbà ijọba fun ‘ra Rẹ:
Ijọba gbogbo gbà Tire,
Nwọn gba b’ Oluwa t’o ṣẹgun.
- Gbogbo ara ọrun, ẹ hó,
At’enia; Oluwa wa,
Ọga ogo t’o gbà ọla
Yio jọba lai ati lai. Amin.