mf Iwo Onidajọ, A fẹrẹ̀ duro na, Pẹlu ayọ̀ tabi ẹ̀ru, Niwaju itẹ̀ Rẹ: Jọ pesè ọkàn wa, Fun ọjọ nlanla nì; p Fi ẹmi irọra kun wa At’ ẹmi adura.
f K’a ma wo ọ̀na Rẹ, L’ akoko aimọ̀ ni; Nigbat’ Iwọ o sọkalẹ̀, Ninu Ọlanla Rẹ. Iwọ ẹni aikú Lati da wa lẹjọ; T’ iwọ ti ogun Baba Rẹ, At’ ore-ọfẹ Rẹ.
mf K’ a lè ba wa bayi Nigbọràn ọrọ Rẹ; K’ a ma tẹti s’ohun ipè, K’ a ma wò ọna Rẹ, K’ a wá ìpo ayọ̀ T’ awọn oluubukun, K’ a si ṣọra nigba diẹ, Fun ‘simi ailopin. Amin.