- mf L”ẹba odo Jordani ní,
Onibaptisi nke wipe;
Oluwa mbọ ! Oluwa mbo!
Ẹ gbọ ‘hin ayọ: Ọba mbo.
- K’ ẹ̀ṣẹ tán ni gbogbo ọkàn,
K’ Ọlọrun ba lè bà wagbé;
K’ a pa ilẹ ọkan wa mọ́
Ki Alejo nla yi to de.
- Jesu, iwọ n’ igbala wa,
Ẹsan, ati alabò wa;
B’itanna l’awa ‘ba ṣegbe
Bikoṣe t’ ore-ọfẹ Rẹ.
- Ṣ’ awotan awọn alaisàn,
Gb’ẹlẹṣẹ t’o ṣubu dide;
Tan ‘mọlẹ Rẹ ka ‘bi gbogbo,
Mu ẹwà aiye bọ́ s’ ipò.
- K’ a f’ iyin f’ Ọmọ Ọlọrun,
Bibọ̀ ẹni ‘mu ‘dande wa;
Ẹni t’ a nsìn pẹlu Baba.
At’ Ọlọrun Ẹmi Mimọ. Amin.