- mf Sunm’ọdọ wa, Emmanuel,
Wá, ra Israeli pada,
p T’ o nṣọ̀fọ li oko ẹru
Titi Jesu y’o tun pada.
ff Ẹ yọ̀, ẹ yọ̀ ! Emmanuel
Y’o wa s’ọdọ wa Israel.
- mf Wá, Ọpa alade Jesse,
K’o gbà wa l’ọwọ ọta wa
Gbà wa lọw’ ọrun apadi
Fun wa ni ‘ṣẹgun l’ori ‘ku,
ff Ẹ yọ̀, ẹ yọ̀, &c.
- Sunmọ wa, “Wọ Ila-orùn,
Ki bibọ̀ Rẹ ṣe ‘tunu wa.
Tú gbogbo iṣudẹ̀de ka.
M’ ẹ̀ṣẹ ati ègbe kuro.
ff Ẹ yọ̀, ẹ yọ̀, &c.
- mf Wa Ọmọ ‘lẹkun Dafidí,
‘Lẹkun ọrun y’o ṣi fun Ọ;
Tùn ọ̀na oṣì fun wa,
Jọ se ọ̀na oṣì fun wa:
ff Ẹ yọ̀, ẹ yọ̀, &c.
- mf Sunmọ wa Oluwa ipá,
T’ o f’ ofin fun enia Rẹ
Nigbani l’ or’ oke Sinai,
‘Nu ẹ̀ru at’ agbara nla
ff Ẹ yọ̀, ẹ yọ̀, &c. Amin.