- f Ará mi fun’ rugbin rere,
Nigba ifunrugbin wa,
Ma ṣiṣẹ l’orukọ Jesu,
Tit’ On o tun pada wá
ff Nigbana ni a o f’ ayọ̀ ka a,
Olukore a kó wọn si abà.
- f Olugbala paṣẹ wipe,
“Ṣiṣẹ nigbat; o j’ ọsán;”
Oru mbowa,” mura giri,
Oloko fẹrẹ̀ de na
ff Nigbana ni, &c.
- T’agba t’ewe jumọ ke, pe,
“Wọ l’ oluranlọwọ wa;
Mu ni funrugbin igbagbọ,
K’a s’eso itẹwọgba.
ff Nigbana ni, &c.
- mf Lala iṣẹ fẹrẹ̀ d’opin,
Ọwọ wa fẹ̀ ba ère;
B’o de ninu Ọlanla Rẹ̀,
Y’o sọ fun wa pe, “Ṣiwọ.”
ff Nigbana ni a o f’ ayọ ka a,
Olukore a kó wọn si abà.