- Ọlọrun, d’ Ọba si,
K’Ọba k’o pẹ́ titi,
Dá, Ọba si.
Jọ, fun ni iṣẹgun,
Irọra at’ ogo,
K’ o jọba pẹ́ titi,
Dá, Ọba si.
- Dide, Ọlọrun wa,
T’ awọn ọta rẹ̀ ká,
Bì wọn ṣubu.
Mu idamu bá wọn,
Fọ́ ‘gbá rikíṣi wọn,
Iwọ l’a gbẹkẹle,
Jare gbà wa.
- Fi ẹ̀bun rere Rẹ
Tẹ́ Ọba wa lọrùn,
K’o pẹ́ titi.
K’ o duro ti ofin,
K’ a le ma f’ ayọ wí
Lati ọkàn wa pe,
Dá Ọba si. Amin.