- f Krist, Ologo, Ọlọla,
Iwọ imọlẹ aiye,
Orùn ododo, dide,
K’o si bori okunkun;
‘Mọlẹ orọ̀, sunmọ mi,
‘Rawọ̀ orọ̀, w’aiya mi.
- p Okùnkun l’owurọ jẹ
B’ Iwọ kò pẹlu rẹ̀ wa;
Ailayọ̀ l’ọjo yi jẹ,
cr B’ anu kò tàn ‘mọlẹ mi,
Fun mi n’ imọlẹ, Jesu,
M’ ọkàn mi gbogbo gbona.
- mf Wá bẹ̀ ọkàn mi yi wò,
Lé okùnkun ẹṣẹ lọ:
F’ imọlẹ ọrun kún mi,
Si tù aìgbagbọ mi ka,
Ma f’ara Rẹ hàn mi sì,
f Si ma ràn b’ ọsangangan. Amin.