mf F’ awọn Ijọ ti nsimi, Awa Ijọ t’ aiye; A f’ iyìn gbogbo fun Ọ, Jesu Olubukun; cr Oluwa, O ti ṣẹgun, Ki nwọn ba le ṣẹgun; f ‘Mọlẹ ade ogo wọn, Lat’ ọdọ Rẹ wa ni.
St. Anderu. mf A yin Ọ, fun ‘ranṣẹ Rẹ, Ti o kọ j’ ipè Rẹ: T’o mu arakọnrin rẹ̀ Wa, lati ri Kristi; cr Pese ọkàn wa silẹ, K’a ṣọna lọdun yi, K’a m’ awọn ará wa wá, Lati ri bibọ̀ Rẹ.
St. Tomasi. mf A yìn Ọ, fun ‘ranṣẹ Rẹ, T’ iṣiyemeji rẹ̀ F’ ẹsẹ̀ ‘gbagbọ wa mulẹ̀, T’ o si fi ‘fẹ Rẹ hàn; p Oluwa f’ alafia F’ awọn ti nreti Rẹ; cr Jẹ k’a mọ Ọ lotitọ, L’ enia at’ Ọlọrun.
St. Stefanu. mf A yin Ọ, fun ‘ranṣẹ Rẹ, Ajeriku ‘kini: Ẹni, ninu wahala, T’o nkepe Ọlọrun; di Oluwa, b’o ba kàn wa Lati jiya fun Ọ, cr L’aiye, jẹ k’a jẹri Rẹ, L’ọrun, jẹ k’a gb’ ade.
St. Johannu Onihinrere. mf A yin Ọ, fun ‘ranṣẹ Rẹ L’ erekuṣu Patmo, A yin Ọ, f’ ẹri totọ, Ti o jẹ́ nipa Rẹ. A yìn Ọ, fun iran na, Ti O fihan fun wa; mp A o fi surù duro, K’ a le kà wa mọ wọn.
Ọjọ awọn Ọmọ wẹrẹ ti a pa. mf A yin Ọ, f’awọn ewe, Ajeriku mimọ; A ṣí wọn lọwọ ogun, Lọ sibi isimi; Rakẹli, má sọkun mọ, Nwọn bọ́ lọwọ ‘rora: cr F’ ọkàn aìlẹ́tàn fun wa, K’ a gb’ ade bi ti wọn.
Iyipada ti St. Paulu. f A yìn Ọ, fun imọlẹ At’ ohùn lat’ ọrun, A si yin Ọ, fun iran, Ti abinuku ri; Ati fun ‘yipada rẹ̀, A fi ogo fun Ọ mf Jọ, tan ina Ẹmi Rẹ, Sinu okunkun wa.
St. Mattia. mf Oluwa, Iwọ t’ o wà, Pẹl’ awọn t’ o pejọ; Iwọ t’o yàn Mattia Lati rọpo Juda: A’ mbẹ Ọ, gbà Ijọ Rẹ cr Lọwọ eke woli; Rant’ ileri Rẹ, Jesu, Pẹlu ‘jọ Rẹ dopin. St. Marku. f A yin Ọ fun ‘ranṣẹ Rẹ, T’ Iwọ f’ agbara fun; Ẹnit’ ihinrere rẹ̀ Mú orin ‘ṣẹgun dùn; Ati n’nu ailera wa, mf Jọ jẹ́ agbara wa; Jẹ k’a s’ eso ninu Rẹ, Iwọ Ajarà wa.
St. Filippi ati St. Jakọbu. mf A nyin Ọ fun ‘ranṣẹ Rẹ, Filippi amọna; Ati f’ arakọnrin Rẹ, Ṣe wa l’arakọnrin; cr Maṣai jẹ k’ a le mọ Ọ, Ọna, Iye, Otọ; f K’a jẹju ko idanwo, Titi ao fi ṣẹgun.
St. Barnaba. mf A nyin Ọ, fun Barnaba, Ẹnit’ ifẹ Rẹ mu K’o kọ ‘hun aiye silẹ, K’o wa ohun ọrun; cr Bi aiye ti ngbilẹ si, Ran ẹmi Rẹ si wa, Ki itunu Rẹ totọ, Tàn bo gbogbo aiye.
St. Johannu Baptisti. A yin Ọ, f’ Oni-baptis, Aṣaju Oluwa; Elija totọ ni ‘ṣe, Lati tùn ọ̀na ṣe. Woli t’o ga julọ ni, O ri owurọ Rẹ; mf Ṣe wa l’ alabukunfun, Ti nreti ọjọ Rẹ.
St. Peteru. f A yin Ọ, fun’ranṣẹ Rẹ, Ogboiya ninu wọn; di O sebu nigba mẹta, O ronupiwada; mf Pẹlu awọn alufa, Lati tọju agbo; Si fun wọn ni igboiya At’ itara pẹlu.
St. Jakọbu. mf A yin Ọ, fun ‘ranṣẹ Rẹ, Ẹniti Herod pa; O mu ago ìyà Rẹ, O mú ọrọ Rẹ ṣẹ; K’ a kọ̀ iwara silẹ, K’ a fi suru duro; K’a kà ìyà si ayọ, B’o ba fà wa mọ Ọ.
St. Bartolomeu. mf A yin Ọ, fun ‘ranṣẹ Rẹ, Ẹni olotọ nì; Ẹnit’ oju Rẹ ti rí, Labẹ ‘gi ọpọtọ. cr Jọ, ṣe wa l’ alailẹtàn, Israeli totọ; Ki O le ma ba wa gbe, K’ O ma bọ́ ọkàn wa.
St. Matteu. mf A yin Ọ, fun ‘ranṣẹ Rẹ, T’o sọ ti ibí Rẹ; T’o kọ̀ ‘hun aiye silẹ, T’o yàn ọna ìyà; Jọ, da ọkàn wa nidè, Lọwọ ifẹ owó; cr Jẹ k’a le jẹ ipè Rẹ, K’a nde k’a tẹle Ọ.
St. Luku. mf A yin Ọ, f’ oniṣẹgun, Ti Ihinrere rẹ̀, Fi Ọ han b’ Oniṣẹgun, At’ Abanidarò: Jọ, f’ororo iwosan, Si ọkàn gbogbo wa, At’ ikunra ‘yebiye, Kùn wa nigbagbogbo.
St. Simoni ati St. Juda. mf F’awọn iranṣẹ Rẹ yi, A yin, Ọ, Oluwa; Ifẹ kanna l’o mu wọn, Lati gb’ ọna mimọ; cr Awa iba le jọ wọn, Lati gbe Jesu ga: p Ki ifẹ só wa ṣọkan, K’a de ibi ‘simi.
IPARI (GENERAL ENDING). f Apọstil, Woli, Martyr, Awọn ẹgbẹ mimọ; Nwọn ko dẹkun orin wọn, Nwọn wọ̀ aṣọ àla; di F’awọnyi t’o ti kọja, A yin Ọ, Oluwa; cr Ao tẹle ipasẹ wọn, A o si ma sin Ọ.
ff Iyin f’ Ọlọrun Baba, At’Ọlọrun Ọmọ, Ọlọrun Emi Mimọ, Mẹtalọkan Mimọ; Awọn ti a rà pada, Y’o tẹriba fun Ọ; Tirẹ l’ọlá, at’ ipá, At’ ogo, Ọlọrun. Amin.