mp Ẹ tun wọn kọ fun mi ki ngbọ, Ọ̀rọ ‘yanu t’ Iye! Jẹ ki nsi tùn ẹwà wọn ri, Ọ̀rọ ‘yanu t’ Iye! Ọ̀rọ ìye at’ ẹwà, ti nkọ́ mi n’ igbagbọ! Ọ̀rọ didun ! Ọrọ ‘yanu! Ọ̀rọ ‘yanu t‘ Iye.
f Kristi nikan lo nfi funni, Ọ̀rọ ‘yanu t’ Iye! Ẹlẹṣẹ, gbọ ‘pè ifẹ na, Ọ̀rọ ‘yanu t’ Iye! L’ọfẹ l’a fifun wa, k’o le tọ́ wa s’ọrun! ff Ọrọ didun! Ọ̀rọ ‘yanu, &c.
f Gbè ohùn Ihinrere na, Ọrọ ‘yanu t’ Iyé! F’ igbala lọ̀ gbogbo enia, Ọ̀rọ ‘yanu t’ Iyè! Jesu Olugbala, wẹ̀ wa mọ́ titi lai! ff Ọ̀rọ didun ! Ọrọ ‘yanu! Ọ̀rọ ‘yanu t‘ Iye. Amin.