f Ore-ọfẹ ! ohùn Adùn ni l’eti wa: Gbohun-gbohun rẹ̀ y’o gbà ọrun kan, Aiye o gbọ pẹlu. f Ore-ọfẹ ṣa, N’ igbẹkẹle mi; p Jesu ku fun araiye, pp O ku fun mi pẹlu.
f Ore-ọfẹ lo kọ, Orukọ mi l’ọrun; L’o fi mi fun Ọdagutan, T’o gbà ìya mi jẹ.
Ore-ọfẹ tọ́ mi S’ọna alafia; O ntọju mi lojojumọ, Ni irìn ajo mi.
Ore-ọfẹ kọ́ mi, Bi a ti ‘gbadurà; O pa mi mọ titi d’ oni, Kò si jẹ ki nṣako.
f Jẹ k’ ore-ọfẹ yi F’ agbara f’ ọkàn mi; Ki nle fi gbogbo ipa mi At’ ọjọ mi fun Ọ. f Ore-ọfẹ ṣa, N’ igbẹkẹle mi; p Jesu ku fun araiye, pp O ku fun mi pẹlu. Amin.