f Oluwa, emi sa ti gbohun Rẹ, O nsọ ifẹ Rẹ si mi: Ṣugbọn mo fẹ nde l’apá igbagbọ, Ki nle tubọ sunmọ Ọ. mf Fà mi mọra, mọra, Oluwa, Sib’ agbelebu t’O ku. Fà mi mọra, mọra, mọra, Oluwa, Sib’ ẹjẹ Rẹ t’o niye.
f Yà mi si mimọ fun isẹ Tirẹ, Nipa ore-ọfẹ Rẹ: Jẹ ki nfi ọkàn igbagbọ w’oke, K’ ifẹ mi tẹ̀ si Tirẹ. mf Fà mi mọra, &c.
A ! ayọ̀ mimọ ti wakati kan, Ti mo lò nib’ itẹ Rẹ, ‘Gbà mo gbadurà si Ọ Ọlọrun, Ti a sọ̀rọ bi ọrẹ́; mf Fà mi mọra, &c.
f Ijinlẹ ifẹ mbẹ ti nkò le mọ̀, Titi ngo fi kọja odò; Ayọ̀ giga ti emi kò le sọ, Titi ngo fi dé ‘simi. mf Fà mi mọra, &c. Amin.