mf ‘Wọ ọ̀rọ t’o dùn julọ, Ninu eyit’ a ri Ileri at’ imuṣẹ Awamaridi ni: p Nigba ẹkún at’ ayọ̀, di ‘Yemeji at’ ẹ̀ru, p Mo gbọ Jesu wipe, “Wa,” Mo si lọ sọdọ Rẹ̀. f Wa, wa sọdọ Mi, Wa, wa sọdd Mi, Alarẹ̀ t’ọrùn nwọ̀, Wa ! Wa sọdọ Mi.
mp Ẹmi mi, má ṣako lọ Kuro lọd’ Ọrẹ yi! Sunmọ Ọ, a! sunmọ Ọ, Ba gbé titi d’opin; p A! alailera l’emi, Ẹṣẹ mi papọju; Mo nṣako nigbagbogbo, Mo si tun pada wa. f Wa ! wa sọdọ Mi ! &c.
mp Ma fà mi sunm’ ọdọ Rẹ, Ki “Wa” yi ba le jẹ Ohùn ti a fọ jẹjẹ F’ ẹni t’o sunmọ Ọ; Okun ati oke nla Kì yio da mi duro Lati dì ọwọ Rẹ mu, Nigbat’ O wipe, “Wa.” f Wa ! wa sọdọ Mi ! &c. Amin.