- f Wá iwọ Jesu t’ a nreti
T’ a bi lati da ni n’ dè,
Gbà wa lọw’ ẹ̀ru at’ ẹ̀ṣẹ,
Jẹ k’ a ri isimi rẹ:
- Iwọ ni itunu Israel,
Ireti Onigbagbọ;
Ifẹ gbogb’ orilẹ-ede
Ayọ ọkàn ti nwọ̀na.
- ‘Wọ t` a bi lati gbà wa là,
Ọmọ ti a bi l’Ọba;
Ti a bi lati jọba lai,
Jẹ ki ijọba Rẹ de:
- Fi Ẹmi Mimọ̀ Rẹ nikan,
Ṣe akoko aiya wa;
Nipa itoye kikun Rẹ,
Gbe wa s’ori itẹ Rẹ. Amin.