- mf Wò bi awa enia Rẹ
p Ti wolẹ l’ ẹsẹ Rẹ;
Ọlọrun ! kiki ànu Rẹ
Ni igbẹkẹle wa.
- f Idajọ t’o ba ni lẹrù,
Nfi agbara Rẹ hàn;
Sibẹ, anu da ‘lu wa si,
Awa si ngbadura.
- mf Ọlọrun, o ṣe da wa si,
Awa alaimore?
Jọ, jẹ k’a gbọ́ ikilọ Rẹ,
Nigbati anu wà.
- Iwa buburu ti pọ to,
Yika ilẹ wa yi !
‘Bukun ilẹ wa lo to yi !
Wo b’ o ti buru to.
- f Oluwa, fi ore ọfẹ
Yi wa l’ ọkàn pada !
Ki a lè gbà ọrọ Rẹ gbọ́,
K’ a si wá oju Rẹ. Amin.