mf Olugbala gbohùn mi, Gbohùn mi, gbohùn mi; Mo wá sọdọ Rẹ, gbà mi, p Nibi agbelebu. di Emi ṣẹ̀, ṣugbọn, O ku; Iwọ ku, Iwọ ku; Fi anu Rẹ pa mi mọ, Nibi agbelebu. f Oluwa, jọ gbà mi, Nk’ y’o bi Ọ ninu mọ́ ! Alabukun, gbà mi, Nibi agbelebu.
p Bi ngo ba tilẹ ṣegbe, Ngo bẹ̀bẹ ! Ngo bẹ̀bẹ ! Iwọ li ọ̀na ìye, p Nibi agbelebu. Ore-ọfẹ Rẹ t’ a gbà, Lọfẹ ni ! Lọfẹ ni ! F’ oju anu Rẹ wò mi, Nibi agbelebu. f Oluwa, jọ, &c.
f F’ ẹjẹ mimọ Rẹ wẹ̀ mi, Fi wẹ̀ mi ! fi wẹ̀ mi ! Rì mi sinu ibu rẹ̀, p Nibi agbelebu. ‘Gbagbọ l’ o le fun wa ni ‘Dariji ! ‘Dariji ! Mo f’ igbagbọ rọ̀ mọ Ọ, Nibi agbelebu. f Oluwa, jọ, &c. Amin.