f Ma koja mi, Olugbala, Gbọ adurà mi; ‘Gbat’ Iwọ ba np’ ẹlomiran, di Maṣe kọja mi ! f Jesu ! Jesu ! Gbọ adurà mi ! Gbat’ Iwọ ba np’ ẹlomiran, Maṣe kọja mi.
p N’ itẹ-anu, jẹ k’emi ri Itura didùn; p Tẹdùntẹdùn ni mo wolẹ, Jọ ràn mi lọwọ. f Jesu ! Jesu ! &c.
f N’ igbẹkẹle itoye Rẹ, L’ em’ o w’ oju Rẹ; p Wò ‘banujẹ ọkàn mi sàn, F’ ifẹ Rẹ gbà mi. f Jesu ! Jesu ! &c.
mf ‘Wọ orisun itunu mi, Jù ‘yè fun mi lọ; Tani mo ni laiye lọrun, Bikoṣe Iwọ? f Jesu ! Jesu ! &c. Amin.