- mf Jesu, o ha le jẹ bẹ pe,
p Ki ẹni kiku tiju Rẹ?
Tiju Rẹ! – Wọ t’ Angẹli nyìn,
Ogo Ẹni nràn titi lai !
- Ki ntiju Jesu ! O ya sẹ
Ki alẹ tiju ìrawọ̀:
On ni ntàn imọlẹ ọrun
Sinu ọkàn okunkun mi.
- Ki ntiju Jesu ! Ọ̀rẹ́ ní,
Ẹni mo nwò lati d’ọrun;
Ewọ̀:-- nigba mo ba ntiju,
Ki nye bọ̀wọ f’okọ Rẹ̀ kọ?
- Ki ntiju Jesu ! emi le,
Bi nkò l’ẹṣẹ lati wẹ̀nu;
Ti nkò ni tọrọ ire kan;
Ti nkò l’ọkàn lati gbala.
- Bi bẹkọ --- mo nhalẹ lasan;
Lasan kọ́ l’Olugbala ku;
p A! k’eyi jẹ iṣogo mi
Pe, Jesu kò si tiju mi. Amin.