- mf Ẹnit’ O la ‘ju afọ́ju,
Ti O mu òpe gbọ́n,
At’ ẹnit’ O dá imọlẹ,
Fun ẹni okunkun.
- Ẹnit’ O le fi agbara
F’ awọn olokunrun,
Ti O si fi ẹmi ìye,
p Fun awọn t’o ti ku.
- Ẹni fi ‘dasilẹ f’ọkàn,
T’O gb’ẹni ṣubu nde,
T’O si pa ibinujẹ dà
S’ orin pẹlu iyìn.
- f Wọ Oniṣegùn ọkàn mi,
Si Ọ l’ awa nkọrin,
Titi aiye o fi d’opin,
Tirẹ l’ọpẹ o ṣe. Amin.