- mp Òtoṣi ẹlẹṣẹ ni mi,
Mo l’ọrẹ Alagbara kan
Olugbala l’orukọ Rẹ̀;
Ifẹ Tirẹ̀ kò nipekun.
- O ri mo ṣina kakiri,
O mu mi wọ̀ agbo Rẹ̀ wa,
O fi ẹjẹ mimọ rà mi.
O si ṣẹgun ọta fun mi.
- f O mu ọkàn mi yọ̀ wipe,
Nisisiyi l’emi o wà
Pẹlu Rẹ̀ l’ori ‘tẹ l’ọrun;
Ore-ọfẹ yi ti pọ̀ to! Amin.