- mp Igba arò ati ayọ̀
Lọwọ Rẹ ni o wà,
Itunu mi t’ọwọ Rẹ wá,
O so lọ l’aṣẹ Rẹ.
- Bi O fẹ gbà wọn lọwọ mi,
Emi ki o binu;
Ki emi ki o to ni wọn,
Tirẹ ni nwọn ti ṣe.
- Emi kì y’o sọ buburu,
B’ aiye tilẹ̀ fò lọ;
Emi o w’ayọ̀ ailopin,
Ni ọdọ Rẹ nikan.
- p Kil’ aiye ati ẹkún rẹ̀?
Adun kikoro ni;
‘Gbati mo fẹ já itanna,
Mo b’ẹgun èṣuṣu.
- Pipe ayọ̀ kò si nihin,
Ororò dà l’oyin;
f Larin gbogbo ayidà yi,
ff ‘Wọ ma ṣe gbogbo mi. Amin.