- mf Awa fẹ ohun aiye yi,
Nwọn dara l’oju wa;
A fẹ k’a duro pẹ titi,
Laifi wọn silẹ lọ.
- Nitori kini a nṣe bẹ?
Aiye kan wà loke;
Nibẹ l’ ẹ̀ṣẹ on buburu
Ati ewu kò si.
- Aiye t’o wà loke ọrun,
Awa iba jẹ mọ!
Ayọ̀, ifẹ, inu rere,
Gbogbo rẹ̀ wà nibẹ.
- p Ikú, o wà ni aiye yi;
Kò si loke ọrun;
Enia Ọlọrun wà mbẹ̀,
Ni ayè, ni aikú.
- K’a ba ọ̀na ti Jesu lọ,
Eyi t’O là fun wa;
ff Sibi rere, sibi ‘simi,
cr S’ ile Ọlọrun wa. Amin.