- f Igbala ni, igbala ni
Awa ẹlẹṣẹ nfẹ;
Nitori ninu buburu
T’a ṣe l’ awa nṣègbé.
- Iṣẹ ọwọ wa ti a nṣe,
O nwi nigbagbogbo
mp Pe, igbala kò si nibẹ,
Iṣẹ kò lè gba ni.
- Awa nṣẹbọ, awa nrubọ,
A nkọrin, a si njo;
Ṣugbọn a kò ri igbala
Ninu gbogbo wọnyi.
- Nibo ni igbala gbe wà?
Fi han ni, if han ni:
B’o wa lokè, bi isalẹ,
B’o ba mọ̀, wi fun wa.
- Jesu ni ṣe Olugbala,
Jesu l‘Oluwa wa;
Igbala wà li ọwọ Rẹ̀;
Fun awa ẹlẹṣẹ.
- f Wá nisisiyi, wá tọrọ,
Ifẹ wà ninu Rẹ̀;
Ẹnyin ti o buru l’O npè pe;
ff Ẹ wá gba igbala. Amin.