Hymn 58: Rejoice, all ye believers

Yo, enyin onigbagbo

  1. f Yọ̀, ẹnyin onigbagbọ,
    Jẹ k’ imọlẹ nyin taǹ
    Igba alẹ mbọ̀ tete,
    Oru si fẹrẹ̀ de
    Ọkọ iyawo dide
    O fẹrẹ sunmọle
    Dide, gbadura, ṣọra,
    L’ oru n’ igbe y’o ta.

  2. mp Ẹ bẹ fitila nyin wò,
    F’ ororo sinu wọn;
    Ẹ duro de ‘gbàla nyin
    Ipari ‘ṣẹ aiye;
    mf Awọn oluṣọ nwipe,
    Ọkọ ‘yawo de tan;
    Ẹ pade rẹ̀, b’ o ti mbọ̀,
    Pẹlu orin iyìn.

  3. cr Ẹnyin wundia mimo,
    Gbe ohùn nyin soke
    f Titi, n’nu orin ayọ̀
    Pẹlu awọn Angẹl.
    Onjẹ iyawo ṣe tan,
    ‘Lẹ̀kun na ṣi silẹ,
    ff Dide arole ogo
    Ọkọ iyawo mbọ̀.

  4. mp Ẹnyin ti ẹ nfi suru
    Rù agbelebu nyin,
    f Ẹ o si jọba lailaí
    ‘Gbati ‘ponju ba tan.
    Yi itẹ ogo Rẹ̀ ka
    Ẹ o r’ Ọd’ agutan
    Ẹ o f’ ade ogo nyin
    Lelẹ̀ niwaju Rẹ̀.

  5. mf Jesu, ‘Wọ ireti wa
    F’ara Rẹ hàn fun wa;
    ‘Wọ Orùn t’ a ti nreti
    Ràn s’ ori ilẹ wa
    A gbe ọwọ wa s’okè,
    Oluwa jẹ k’a ri
    Ọjọ ‘rapada aiye
    T’ o mu wa d’ ọdọ Rẹ. Amin.