- mf Ifẹ l’ Ọlọrun, anu Rẹ̀
Tàn si ọ̀na wa gbogbo;
O fun wa ni alafia,
Ifẹ ni Ọlọrun wa.
- p Iku ndoro pupọpupọ,
di Enia si ndibajẹ;
Ṣugbọn anu Rẹ́ wà titi,
Ifẹ ni Ọlọrun wa.
- Lakoko t’o dab’ o ṣokùn
A nri ore Rẹ̀ daju;
O tàn imọlẹ̀ Rẹ̀ fun wa,
Ifẹ ni Ọlọrun wa.
- O so ‘reti, at’ itunu
Mọ aniyàn aiye wa;
Ogo Rẹ̀ ntàn nibigbogbo,
Ifẹ ni Ọlọrun wa. Amin.