APA I- f Salẹm t’ọrun, Ilu ‘bukun,
T’o kun fun ‘fẹ at’ ayọ̀,
Ti a f’okuta aye kọ́,
Ni ọrun giga loke,
Pẹl’ ogun angẹli yika,
T’o nsọkalẹ b’ iyawo.
- Lat’ ode ọrun lọhun wá
L’o ti wọ aṣọ ogo,
T’o yẹ Ẹniti o fẹ ọ,
Ao sìn ọ f’ọkọ rẹ;
Gbogbo ita at’ odi rẹ
Jẹ kiki ọṣọ wura.
- Ilẹkun rẹ ndan fun pearli
Nwọn wà ni ṣíṣi titi;
Awọn olotọ nwọ ‘nu rẹ̀
Nip’ ẹjẹ Olugbala,
Awọn t’o farada ‘pọnju
‘Tori orukọ Jesu.
- Wahala at’ ipọnju nla
L’o ṣ’okuta rẹ lẹwà,
Jesu papa l’ Ẹni tò wọn
S’ipo ti o gbe dara,
Ifẹ inu Rẹ̀ sa ni pe,
K’ a le ṣ’ afin Rẹ̀ l’ọṣọ́.
- ff Ogo at’ ọla fun Baba,
Ogo at’ ọla f’ Ọmọ,
Ogo at’ ọla fun Ẹmi,
Mẹtalọkan titi lai;
At’ aiyeraiye Ọkanna,
Bakanna titi aiye. Amin.
APA II
- mf Kristi n’ ipilẹ t’o daju,
Kristi l’Ori at’ Igunle,
Aṣayan at’ Iyebiye,
O so gbogbo Ijọ lù;
Iranwọ Sionui Mimọ,
Igbẹkẹle rẹ̀ titi.
- mp Si Tẹmpili yi l’ a npe Ọ,
Jọ wá loni, Oluwa;
Ni ọ̀pọ inurere Rẹ,
Gbọ ẹ̀bẹ enia Rẹ;
Ma dà ẹkún ibukun Rẹ
Sinu ile yi titi.
- Fun awọn ọmọ Rẹ l’ẹbùn
Ti nwọn ba tọrọ nihin,
Ore ti nwọn ba sì rí gbà,
K’ o ma jẹ ti wọn titi;
Nikẹhin ninu ogo Rẹ,
Ki nwọn ma ba Ọ jọba.
- ff Ogo at’ọla fun Baba,
Ogo at’ ọla f’ Ọmọ,
Ogo at’ ọla fun Ẹmi,
Mẹtalọkan titi lai,
At’ aiyeraiye, Ọkanna,
Bakanna titi aiye. Amin.