- mf Kristi n’ ipilẹ̀ wa,
Lori Rẹ̀ lao kọle;
Awọn mimọ nikan,
L’o ngb’ agbala ọrun.
Ireti wa
T’ore aiye
T’ ayọ̀ ti mbọ̀,
Wà n’nu ‘fẹ Rẹ̀.
- f Agbalá mimọ́ yi,
Y’o hó f’ orin ìyin,
Ao kọrin ìyin si,
Mẹtalọkan mimọ́.
Bẹ lao f’ orin
Ayọ̀ kede
Orukọ Rẹ
Titi aiye.
- mf Ọlọrun Olore,
Fiyesini nihin;
Lati gba ẹjẹ́ wa,
At’ ẹ̀bẹ wa gbogbo;
K’o si f’ ọpọ̀
Bukun dahun
Adura wa
Nigbagbogbo.
- cr Nihin, jẹ k’ ore Rẹ
T’a ntọrọ l’at’ ọrun,
Bọ s’ori wa lẹkan,
K’o má si tun lọ mọ.
di Tit’ ọjọ na
T’ao ṣ’akojọ
p Awọn mimọ́
Sib’ isimi. Amin.