Hymn 575: We lay down this foundation, Lord

A fi ipile yi le’ le

  1. mf A fi ipilẹ̀ yi le ‘lẹ̀,
    Ni orukọ Rẹ Oluwa,
    Awa mbẹ̀ ọ, Oluwa wa.
    Ma tọju ibi mimọ́ yi.

  2. Gba enia Rẹ ba nwá Ọ,
    T’ẹlẹṣẹ nwá Ọ, n’ ile yi,
    Gbọ́, Ọlọrun lat’ ọrun wa,
    F’ ẹ̀ṣẹ wọn jì wọn, Ọlọrun.

  3. ‘Gb’ awọn Alufa ba nwasu
    Ihinrere ti Ọmọ Rẹ;
    Ni orukọ Rẹ̀, Oluwa,
    Ma ṣiṣẹ iyanu nla Rẹ.

  4. ‘Gb’ awọn ọmọde ba si nkọ
    f Hosèanna si Ọba wọn;
    cr Ki Angẹl ba wọn kọ pẹlu,
    K’ ọrun at’ aiye jọ gberin.

  5. Jehofah o ha ba ni gbe,
    Ni aiye buburu wa yi?
    Jesu o ha jẹ Ọba wa,
    Ẹmi o ha simi nihin?

  6. f Má jẹ ki ogo Rẹ kuro
    Ninu ile ti a nkọ yi;
    Ṣe ‘jọba Rẹ ni ọkàn wa,
    Si tẹ itẹ Rẹ sinu wa. Amin.