- mp Ọrọ alafia,
La fi sìn nyin, ará,
cr K’ alafia bi odo nla,
Ma ba nyin lọ.
- mp N’nu ọ̀rọ adura,
A f’ awọn ará wa
Le iṣọ́ Oluwa lọwọ,
Ọrẹ́ totọ.
- mf Ọrọ ifẹ didùn,
L’a fi p’ odigboṣe;
Ifẹ wa ati t’ Ọlọrun,
Y’o ba wọn gbe.
- f Ọrọ gbagbọ lile,
Ni igbẹkẹle wa;
Pe, Oluwa y’o ṣe ranwọ,
Nigba gbogbo.
- Ọrọ ‘reti didun,
Y’o mu ‘pinyà wa dùn;
Y’o sọ ayọ̀ t’o lè dùn jù
Ayọ t’ aiye.
- mf Odigboṣe, ará,
N’ ifẹ at’ igbagbọ;
p Tit’ ao fi tun pade lokè,
N’ il wa ọrun. Amin.