Hymn 573: Eternal Father, strong to save

Baba wa, Olodumare

  1. mf Baba wa, Olodumare,
    ‘Wọ t’o kawọ ìgbin omi,
    ‘Wọ t’o ti f’ipò okun fun,
    Ti kò lè ré ibẹ kọja;
    p.cr Gbọ́ tiwa, gbat’ a nkepè Ọ,
    di F’ awọn t’o wà loju omi.

  2. mf Olugbala, ‘Wọ t’ọ̀rọ Rẹ̀
    Mu ìgbi omi pa rọrọ,
    Iwọ t’o rìn l’ ori omi,
    T’o sùn b’ ẹnipe kò si nkan;
    p.cr Gbọ́ tiwa, gbat’ a nkepè Ọ,
    di F’ awọn t’o wà loju omi.

  3. mf ‘Wọ Emi Mimọ t’o radọ̀
    B’omi aiye nijọ kini;
    T’o mu ‘binu rẹ̀ pa rọrọ.
    Oluwa ‘mọlẹ at’ iye;
    p.cr Gbọ́ tiwa, gbat’ a nkepè Ọ,
    di F’ awọn t’o wà loju omi.

  4. f Mẹtalọkan, Alagbara,
    Dabobo wọn ninu ewu;
    Lọwọ apata at’ ìji,
    Lọwọ ina ati ọtá;
    ff Si jẹ k’a ma kọrin ‘yìn Rẹ,
    di L’ or’ ilẹ̀ ati lor’ omi. Amin.