- Baba, jọwọ gb’ adurà wa,
Bi a ti nlọ loju omi;
Iwọ ma jẹ ebute wa
At’ ile wa loju omi.
- p Jesu Olugbala, ‘Wọ ti
O ti mu ‘jì dakẹ rọrọ;
cr Ma jẹ ayọ̀ fun aṣọ̀fọ,
F’ isimi f’ ọkàn aibalẹ̀.
- mf ‘Wọ Ẹmi Mimọ́, Ẹniti
O ràbaba loju omi,
Paṣẹ ‘bukun l’akoko yi
Fi ipá Rẹ mu wa sọji.
- f ‘Wọ Ọlọrun Mẹtalọkan,
Ti awa nsìn, ti awa mbọ;
Ma ṣe ‘bi ‘sadi wa l’aiye,
Ati ayọ wa li ọrun. Amin.