- f Tẹrutẹru t’ iyanu ni
Ọlọrun mi da mi,
Gbogb’ awọn ẹ̀ya ara mi,
Iṣẹ iyanu ni.
- Nigbat’ a da mi n’ ikọkọ,
O ti mọ̀ ara mi;
Ẹyà ara mi l’O si mọ̀,
Sa t’ ọkan wọn kò si.
- Ọlọrun, iro inu Rẹ,
Ṣe ‘yebiye fun mi;
Iye wọn pọju iyanrin,
Ti a kò lè kaye.
- B’o ti mọ̀ ẹda mi bayi,
Wadi ọkàn temi;
Mu mi mọ̀ ọ̀na Rẹ lailai.
Si ma tọ́ ẹsẹ mi. Amin.