- mf Oluwa, Iwọ wadi mi,
Em’ iṣẹ ọwọ Rẹ;
Ijoko on idide mi,
Kò pamọ loju Rẹ.
- N’ ile mi, ati l’ọna mi,
N’ Iwọ ti yi mi ka;
Kò s’irò tabi ọ̀rọ mi,
T’ Iwọ kò ti mọ̀ tan;
- mf Niwaju ati lẹhin mi,
N’ Iwọ ti se mi mọ;
Iru ‘mọ̀ yi ṣe ‘yanu jù,
Ti emi kò lè mọ̀.
- Lati sá kuro loju Rẹ,
Iṣ’ asan ni fun mi,
Ẹmi Rẹ lu aluja mi,
Bẹ ni mo sá lasan.
- mp Bi mo sá sinu okunkun,
Asan ni eyi jẹ;
Imọlẹ l’ okunkun fun Ọ,
B’ ọsangangan l’o ri.
- Bi Iwọ ti mọ̀ ọkàn mi,
Lat’ inu iyá mi;
Jẹ ki emi k’o f’ara mi
Fun Ọ Olugbala. Amin.