Hymn 57: Behold see yonder horizon;

Wo oju sanma ohun ni

  1. mf Wò oju sanma ọ̀hun nì
    Wo lilà orùn orọ̀;
    f Ji l’ oju orun, ọkàn mi,
    Dide k’ o si ma ṣọra;
    Olugbala, Olugbala,
    Tun npada bọ̀ wá saiye.

  2. O pẹ ti mo ti nreti Rẹ,
    L’arẹ̀ l’ ọkàn mi nduro,
    Aiye kò ni ayọ̀ fun mi,
    Nibiti kò tàn ‘mọlẹ̀.
    Olugbala, Olugbala,
    ‘Gbawo ni ‘Wọ o pada?

  3. mf Igbala mi sunm’ etile,
    Oru fẹrẹ̀ kọja na,
    p Jẹ ki nwà n’ ipò irẹlè,
    Ki nṣ’ afojusọna Rẹ.
    Olugbala, Olugbala,
    Titi ngo fi r’ oju Rẹ

  4. mf Jẹ ki fitila mi ma jo,
    p Ki mmà ṣako kiri mọ,
    Ki nsa ma reti àbo Re,
    Lati mu mi lọ s’ ile;
    Olugbala, Olugbala,
    ff Yara k’ o ma bọ` kànkàn. Amin.