- f Ọkàn mi, yìn Ọba ọrun,
Mu ọrẹ wa s’ọdọ Rẹ̀;
mp ‘Wọ t’a wòsan t’a dariji,
cr Tal’ a ba ha yìn bi Rẹ̀?
f Yìn Oluwa, yìn Oluwa,
Yin Ọba ainipẹkun.
- mf Yin, fun anu t’O ti fihàn,
F’awọn baba ‘nu pọnju;
Yìn I, ọkan nà ni titi,
O lọra lati binu:
f Yìn Oluwa, yìn Oluwa,
Ologo n’nu otitọ.
- p Bi baba ni O ntọju wa,
O si mọ̀ ailera wa;
Jẹjẹ l’o ngbe wa l’apa Rẹ̀,
O gbà wa lọwọ ọ̀ta;
f Yìn Oluwa, yìn Oluwa,
Anu rẹ̀ yi aiye ka.
- A ngbà b’ itàná eweko,
T’ afẹfẹ nfẹ, t’o si nrọ;
p ‘Gbati a nwà, ti a si nkú,
Ọlọrun wà bakannà;
f Yìn Oluwa, yìn Oluwa,
Ọba alainipẹkun.
- ff Angẹl, ẹ jumọ ba wa bọ,
Ẹnyin nri lojukoju;
Orùn, oṣupa, ẹ wolẹ̀,
Ati gbogbo agbaiye.
Ẹ ba wa yìn, Ẹ ba wa yìn
Ọlọrun Olotitọ. Amin.