- f Ji, ọkàn mi, dide layọ̀,
Kọrin iyìn Olugbala;
Ọla Rẹ̀ bere orin mi:
p ‘Ṣeun ifẹ Rẹ̀ ti pọ̀ to !
- O ri mo ṣegbe n’ iṣubu,
Sibẹ, O fẹ mi l’ afẹtan;
O yọ mi ninu òṣi mi:
p ‘Ṣeun ifẹ Rẹ̀ ti pọ̀ to !
- Ogun ọta dide si mi,
Aiye at’ Eṣu ndèna mi,
On nmu mi là gbogbo rẹ̀ ja;
‘Ṣeun ‘fẹ Rẹ̀ ti n’ipa to !
- .f ‘Gba ‘yọnu de, b’ awọsanma,
T’o ṣu dùdù t’o nsan ará;
O duro tì mi larin rẹ̀:
‘Ṣeun ‘fẹ Rẹ̀ ti dara to !
- ‘Gbagbogbo l’ ọkàn ẹṣẹ mi
Nfẹ yà lẹhìn Oluwa mi;
Ṣugbọn bi mo ti ngbagbe Rẹ̀,
Iṣeun ifẹ Rẹ̀ ki yẹ̀.
- Mo fẹrẹ f’ aiye silẹ̀ na,
p Mo fẹ bọ́ lọw’ ara iku;
A ! k’ ẹmi ‘kẹhin mi kọrin
Iṣeun ifẹ Rẹ̀ n’ iku.
- Njẹ ki nfò lọ, ki nsì goke,
S’ aiye imọlẹ titi lai;
Ki nf’ayọ̀ iyanu kọrin
Iṣeun ifẹ Rẹ̀ lọrun. Amin.