- f Ewe ti Ọba ọrun,
Kọrin didun b’ẹ ti nlọ;
Kọrin ‘yìn Olugbala,
Ologo n’nu iṣẹ Rẹ̀.
- di A nlọ sọdọ Ọlọrun,
L’ ọ̀na t’ awọn baba rìn;
cr Nwọn si nyọ̀ nisisiyi,
Ayọ̀ wọn l’ awa o ri.
- f Kọrin, agbo kekere,
Ẹ o simi n’itẹ Rẹ̀;
Ib’ a pese ‘joko nyin,
Ibẹ si n’ ijọba nyin.
- cr Woke, ọmọ imọlẹ,
Ilu Sion wà lọkan:
ff Ibẹ̀ n’ile wa titi.
Ibẹ l’a o r’Oluwa.
- Má sá, ẹ duro l’ayọ̀,
Ni eti ilẹ̀ ti nyin;
Kristi Ọmọ Baba nwi
Pe, laifoya k’a ma lọ.
- mf Jesu, a nlọ l’aṣẹ Rẹ;
A kọ̀ ‘hun gbogbo silẹ;
Iwọ ma j’Amọna wa,
A o si ma ba Ọ lọ. Amin.