- mf A kọrin s’Ọmọ Ọlọrun,
p Ọdagutan t’a pa;
Ti ọrun ati aiye mbọ,
T’O yẹ lati jọba.
- Si Ọ l’ awọn Angẹli nke,
L’ ẹkùn gbogbo ọrun;
p “Mimọ́, mimọ́, mim’ Ọlọrun,
T’ ogo, at’ ọm’ ogun.”
- f Ijọ Rẹ li aiye dapọ,
di Lati ma kepe Ọ;
Didan Ọlanla Ọlọrun,
T’ O l’agbara gbogbo.
- Larin wọn ni gbogbo wa nfẹ
Lati yìn ẹjẹ Rẹ;
Jọba l’ aiye ati l’ ọrun,
‘Wọ Ọmọ Ọlọrun. Amin.