Hymn 560: Oh worship the King, all glorious above!

E wole f’Oba, Ologo julo

  1. f Ẹ wolẹ̀ f’Ọba, Ologo julọ,
    Ẹ kọrin ipa ati ifẹ Rẹ̀;
    Alabo wa ni, at’ Ẹni Igbani,
    O ngbe ‘nu ogo, Ẹlẹrù ni iyìn.

  2. Ẹ sọ t’ipa Rẹ̀, ẹ sọ t’ore Rẹ̀;
    ‘Mọlẹ l’aṣọ Rẹ̀, kọ̀bi Rẹ̀, ọrun,
    cr Ará ti nsán ni kẹ̀kẹ́ ‘binu Rẹ̀ jẹ́;
    Ipa ọna Rẹ́ ni a kò si le mọ̀.

  3. mf Aiye yi pẹlu ẹ̀kún ‘yanu rẹ̀,
    Ọlọrun, agbara Rẹ l’o dá wọn;
    O fi idi rẹ́ mulẹ, kò si le yí,
    O si f’okun ṣe aṣọ igunwà Rẹ̀.

  4. cr Ẹnu ha lè sṣ ti itọju Rẹ̀?
    Ninu afẹfẹ, ninu, imọlẹ;
    di Itọju Rẹ̀ wà nin’ odo t’o nṣan,
    p O si wà ninu ìri ati òjo.

  5. mp Awa erupẹ, aw’ alailera,
    cr ‘Wọ l’a gbẹkẹle, O kì o dà ni;
    Anu Rẹ̀ rọnu, o si le de opin,
    f Ẹlẹda, Alabo, Olugbala wa.

  6. ff ‘Wọ Alagbara, Onifẹ Julọ,
    B’awọn angẹli ti nyìn Ọ l’oke,
    di Bẹ l’awa ẹda Rẹ, niwọn t’a le ṣe,
    cr A o ma juba Rẹ, a o ma yìn Ọ. Amin.