- f Jesu t’ o ga julọ l’ ọrun,
Ipá Rẹ l’ o d’ aiye;
‘Wo f’ ogo nlanla Rẹ silẹ,
Latì gbà aiye lá.
- O w’ aiye ninu irẹlè
mf Ni ara oṣi wa;
p Nitori k’ọkàn t’ o rẹlẹ̀
Lè t’ ipasẹ Rẹ là.
- f Wiwá Rẹ ya angẹl l’ẹnu,
Ifẹ t’ o tobi ni;
Enia l’ anfani ìyè
Angẹli ṣẹ̀, kò ni.
- f Njẹ araiye yọ̀; sa nyin de,
ff Ẹ ho iho ayọ̀:
Igbala mbọ fun ẹlẹṣe;
Jesu, Ọlọrun ni.
- Oluwa, jẹ ki bibọ Rẹ,
Nigba ẹrinkeji,
Jẹ ohun ti a nduro dè,
K’ o lè ba wa l’ ayọ̀. Amin.