- f Ẹ gbe ohùn ayọ̀ at’ iyìn ga, Alle|luya!
Orin ogo Ọba nla l’awọn ti a ràpada!
y’o ma kọ:
Alle|luya ! Alle|luya!
- Awọn ẹgbẹ akọ|rin ọrun,
Nwọn o gberin na yi|ka ọrun;
Alle|luya ! Alle|luya!
- p Awọn ti nrìn gbẹ̀fẹ kiri ni Para|dise,
Awọn ẹni ‘bukun ni, nwọn o ma kọ|rin
wipe,
Alle|luya ! Alle|luya!
- mf Awọn ‘ràwọ ti ntàn | mọlẹ wọn,
Ati gbogbo awọn ẹgbẹ irawọ, dà ohùn
wọn | lù wipe.
Alle|luya ! Alle|luya!
- f Ẹnyin sanma t’o nwọ́ si lọ, at’ ẹnyin |
ẹfufu,
Ẹnyin ará t’o nsán wa, | enyin màna-
mána t’o | nkọ mànà;
Ẹ fi a|yọ̀ gberin, Alle|luya !
- Ẹnyin omi, at’ ìgbi okun, ẹnyin òjo,
a| t’ otutù,
Ẹnyin ọjọ dida|ra gbogbo,
Ẹnyin ìgbòrò at’ igbó, ẹ | gberin na,
Alle|luya !
- mf Ẹnyin oniruru ẹiyẹ, ẹ kọrin iyìn Ẹlẹ|da
nyin pe,
Alle|luya ! Alle|luya!
- Ẹnyin ẹranko igbe, ẹ d’o|hùn nyin lù
Ẹ si kọrin iyìn Ẹlẹ|da wipe
Alle|luya ! Alle|luya!
- f Jẹ k’awọn òke k’o | bú s’ayọ̀
Alle|luya !
p K’awọn pẹ̀tẹlẹ si | gberin na,
Alle|luya !
- Ẹnyin ọgbun omi okun, ẹ | kọ wipe,
Alle|luya !
Ẹnyin ilẹ gbigbẹ, ẹ da| hùn wipe,
Alle|luya !
- Ọlọrun t’O | dá aiye, ni k’a | f’orin yìn;
Alle|luya ! Alle|luya!
- Eyi l’orin ti Ọlọ|run wa fẹ,
Alle|luya !
p Eyi l’orin ti Krist tika|larẹ fẹ
Alle|luya !
- Nitorina, tọkàntọkàn l’ao | fi kọrin,
Alle|luya !
Awọn ọmọde wẹwẹ̀wẹ y’o gbà orin
na | kọ wipe
Alle|luya !
- cr Ki gbogbo enia | ki o kọ
Alleluya si | Ọlọrun;
Alleluia ti|ti aiye,
Fun Ọmọ on Ẹ|mi Mimọ.
- ff Ogo ni f’Olo|go Mẹta
Alleluya! Alle|luya ! Alle|luya! Amin.