- mf ‘Wọ, ọ̀wọn Olurapada,
A fẹ ma gburo Rẹ;
Kò s’ orin bi orukọ Rẹ,
T’o lè dun t’ abọ rẹ̀.
- mf A ! a ba lè ma gbohùn Rẹ!
L’ anu sọrọ si wa;
Nin’ Alufa wa l’a o yọ̀,
Mẹlksedẹk giga.
- Jesu ni y’o ṣe orin wa,
Nigbat’ a wà l’aiye;
A o kọrin ifẹ Jesu,
‘Gba nkan gbogbo bajẹ.
- Nigba ‘ba yọ sokè lọhun
Pẹlu ‘jọ, ẹni Rẹ;
ff ‘Gbana a o kọrin kikan,
Krist ni y’o j’ orin wa. Amin.