- f Emi ‘ba n’ẹgbẹrun ahọn,
Fun ‘yin Olugbala,
Ogo Ọlọrun Ọba mi,
Iṣẹgun ore Rẹ̀.
- p Jesu t’O s’ẹrù wa d’ayọ̀,
T’O mu banujẹ tàn;
Orin ni l’eti ẹlẹṣẹ,
cr Iye at’ ilera.
- mf O ṣẹgun agbara ẹ̀ṣẹ,
O dá onde silẹ̀;
di Ẹjẹ Rẹ̀ lè w’eleri mọ,
p Ẹjẹ Rẹ̀ ṣeun fun mi.
- cr O sọ̀rọ, oku gb’ohùn Rẹ̀;
O gbà ẹmi titun;
Onirobinujẹ y’ayọ̀,
Otoṣi si gba gbọ.
- f Odi, ẹ kọrin iyìn Rẹ̀;
Aditi, gbohùn Rẹ̀;
Afọju, Olugbala de,
Ayarọ, fò f’ayọ̀.
- Baba mi at’ Ọlọrun mi,
Fun mi n’iranwọ Rẹ;
ff Ki nle rò ká gbogbo aiye,
Ọlá Orukọ Rẹ. Amin.