Hymn 556: For mercies, countless as the sands

Fun anu to po b’iyanrin

  1. f Fun anu to pọ̀ b’iyanrin,
    Ti mo ngbà l’ojumọ;
    Lat’ọdọ Jesu Oluwa,
    Kil’ emi o fi fun?

  2. p Kini ngo fi fun Oluwa,
    Lat’inu ọkàn mi?
    Ẹṣẹ ti ba gbogbo rẹ̀ je,
    Ko tilẹ jámọ nkan.

  3. cr Eyi l’ohun t’emi o ṣe,
    F’ohun t’O ṣe fun mi;
    Em’o mu ago igbala,
    Ngo kepe Ọlọrun.

  4. mp Eyi l’ọpẹ ti mo le dá,
    Emi oṣi, àre;
    Em’ o ma sọrọọ ẹbun Rẹ̀,
    Ngo si ma bere si.

  5. Emi kò le sin b’o ti tọ́,
    Nko n’iṣẹ kan to pé;
    f Ṣugbọn em’o ṣogo yi pe,
    Gbese ọpẹ mi pọ̀. Amin.