- f Ẹ jẹ k’a f’inu didùn
Yìn Oluwa Olore;
Anu Rẹ̀, O wà titi,
Lododo dajudaju.
- mf On, nipa agbara Rẹ̀,
F’ imọlẹ s’aiye titun;
Anu Rẹ̀, O wà titi,
Lododo dajudaju.
- mf O mbọ́ gbogb’ ẹ̀dá ‘layè,
O npèse fun aini wọn;
Anu Rẹ̀, O wà titi,
Lododo dajudaju.
- cr O bukun ayanfẹ Rẹ̀,
Li aginju iparun;
Anu Rẹ̀, O wà titi,
Lododo dajudaju.
- f Ẹ jẹ k’a f’ inu didun,
Yìn Oluwa Olore;
Anu Rẹ̀, O wà titi,
Lododo dajudaju. Amin.