- f Jẹ k’a f’ohùn kan kọrin,
K’a ma yin Oluwa wa,
O yẹ k’a f’ iyin fun U,
L’ ọkàn ati l’ ohùn wa.
- O f’ agbara Rẹ̀ dá wa,
O pa wa mọ di oni;
p O rà wa lọwọ ikú,
O wá, O si kú fun wa.
- mf Aṣẹ t’O pa ni k’ a ṣe,
Ọna t’O là ni k’a tọ̀;
B’ O ti fẹni, jẹ k’a fẹ
Enia at’ Ọlọrun.
- O fẹ adura ewe,
O si fẹ ìyin ewe;
f Jẹ k’a f’ọkàn wa fun U,
cr A o de ‘lẹ ọba Rẹ̀. Amin.