- f Ẹ jẹ k’a yìn Ọlọrun wa,
Ẹnit’ ‘O wà l’oke ọrun,
T’ O fi onjẹ fun enia,
Ti O si fi fun ẹranko.
- O si tẹ oju ọrun lọ,
O da orùn on oṣupa;
Iṣẹ ọwọ Rẹ̀ n’ irawọ,
Iye wọn awa ko lè kà.
- O si dá ara enia,
O si fun wọn l’ẹmi pẹlu;
O si da ni daradara,
Bi o ti yẹ, bi ‘ba ti wà.
- p Ṣugbọn enia dibajẹ,
Nwọn si bọ́ s’inu buburu
Ere ẹ́ṣẹ ni nwọn si njẹ,
pp Ni wahala ati n’ ikú.
- f Ṣugbọn jẹ k’a yìn Ọlọrun,
On fun wa ni Kristi Jesu:
Lati wá awọn t’o ti nù,
Ninu ẹ̀ṣẹ ti nwọn ti nrin. Amin.