Hymn 55: The Lord is coming world trembles

Oluwa mbo; aiye o mi

  1. f Oluwa, mbọ̀; aiye o mì,
    Oke y’o ṣidi n’ ipo wọn;
    At’ irawọ oju ọrun,
    Y’o mu imọlẹ wọn kuro.

  2. f Oluwa mbọ̀; bakanna kọ
    p Bi o ti wá n’ irẹlẹ ri;
    Ọdọ-agutan ti a pa,
    pp Ẹni-iyà ti o si kú.

  3. f Oluwa mbọ̀, li ẹ̀ru nla,
    L’ ọwọ ina pẹlu ìja
    L’ or’ iyẹ apa Kerubu,
    Mbọ, Onidajọ araiye.

  4. mf Eyi ha li ẹniti nrìn,
    Bi erò l’ opopo aiye?
    Ti a ṣe ‘nunibibi si?
    pp A! Ẹniti a pa l’eyi?

  5. mf Ika; b’ẹ wọ̀ ‘nu apata,
    B’ ẹ wọ̀ nu iho, lasan ni;
    f Ṣugbọn igbagbọ t’o ṣẹgun,
    ff Y’ o kọrin pe, Oluwa de. Amin.